20. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,idà ni a ó fi pa yín run.”Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.
21. Wo bí ìlú òtítọ́ ṣe di àgbèrè!Ó ti kún fún ìdájọ́ òtítọ́ nígbà kan rí,òdodo ń gbé ibẹ̀ tẹ́lẹ̀ ríṣùgbọ́n báyìí o àwọn apànìyàn!
22. Sílífà rẹ ti di ìpẹ́pẹ́,ààyò wáìnì rẹ la ti bomi là.
23. Ọlọ̀tẹ̀ ni àwọn aláṣẹ yín,akẹgbẹ́ àwọn olè,gbogbo wọn ló fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀wọ́n sì ń wá ẹ̀bùn kiri.Wọ́n kì í ṣàtìlẹyìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,ẹjọ́ opó kì í sìí dé iwájú wọn.