Àìsáyà 1:17-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. kọ́ láti ṣe rere!Wá ìdájọ́ òtítọ́,tù àwọn tí a ń pọ́n lójú nínú.Ṣàtìlẹ́yìn fún ẹ̀tọ́ aláìní baba,gbà ẹjọ́ opó rò.

18. “Ẹ wá ní ìsinsìnyìí, ẹ jẹ́ kí a jọ ṣàsàrò,”ni Olúwa wí.“Bí ẹ̀ṣẹ̀ yín bá rí bí osùn,wọn ó sì funfun bí i yìnyín,bí wọn bá sì pọ́n bí ẹ̀jẹ̀,wọn ó sì dàbí ẹ̀gbọ̀n-òwú.

19. Tí ó bá tinú un yín wá tí ẹ sì gbọ́ràn,ẹ̀yin yóò sì jẹ ojúlówó adùn ilẹ̀ náà.

20. Ṣùgbọ́n tí ẹ bá kọ̀ tí ẹ sì ṣọ̀tẹ̀,idà ni a ó fi pa yín run.”Nítorí ẹnu Olúwa la ti sọ ọ́.

Àìsáyà 1