3 Jòhánù 1:6-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Tí wọn ń jẹ̀rìí sí ìfẹ́ rẹ̀ níwájú ìjọ: bí ìwọ bá ń pèsè fún wọ́n ní ọ̀nà àjò wọn gẹ́gẹ́ bí o tí yẹ nínú Ọlọ́run.

7. Nítorí pé nítorí iṣẹ́ Kírísítì ni wọ́n ṣe jáde lọ, láìgbà ohunkóhun lọ́wọ́ àwọn aláìkọlà.

8. Nítorí náà, ó yẹ kí àwa fi inú rere gba irú àwọn wọ̀nyí, kí àwa lè jẹ́ alábáṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.

9. Èmi kọ̀wé sí ìjọ: ṣùgbọ́n Díótíréfè, ẹni tí ó fẹ́ láti jẹ́ ẹni pàtàkì jùlọ, kò gbà wá.

10. Nítorí náà bí mo bá dé, èmi yóò mú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ṣe wá sì ìrántí rẹ, tí ó ń sọ ọ̀rọ̀ búburú àti ìsọkúsọ sí wa: èyí kò sì tún tẹ́ ẹ lọ́rùn, síbẹ̀ òun fúnra rẹ̀ kọ̀ láti gba àwọn ará, àwọn tí o sì ń fẹ́ gbà wọn, ó ń dá wọn lẹ́kun, ó sì ń lé wọn kúrò nínú ìjọ.

3 Jòhánù 1