2 Tímótíù 2:9-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nínú èyí tí èmi ń rí ìpọ́njú títí dé inú ìdè bí arúfin; ṣùgbọ́n a kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

10. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé.

11. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:Bi àwa bá bá a kú,àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.

12. Bí àwa bá faradà,àwa ó sì bá a jọba:Bí àwa bá sẹ́ ẹ,òun náà yóò sì sẹ́ wa.

2 Tímótíù 2