10. Nítorí náà mo ń faradà ohun gbogbo nítorí àwọn àyànfẹ́; kí àwọn náà pẹ̀lú lè ní ìgbàlà tí ń bẹ nínú Kírísítì Jésù pẹ̀lú ògo ayérayé.
11. Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà:Bi àwa bá bá a kú,àwa yóò yè pẹ̀lú rẹ̀.
12. Bí àwa bá faradà,àwa ó sì bá a jọba:Bí àwa bá sẹ́ ẹ,òun náà yóò sì sẹ́ wa.
13. Bí àwa kò bá gbàgbọ́,òun dúró ni olóòótọ́:Nítorí òun kò lè sẹ ara rẹ̀.
14. Nǹkan wọ̀nyí ni ki ó máa rán wọn létí. Máa kìlọ̀ò fún wọn níwajú Olúwa pé, ki wọn ó yẹra kúrò nínú jíjiyàn ọ̀rọ̀ tí kò léèrè, bí kò ṣe ìparun fún àwọn tí ń gbọ́.