2 Tímótíù 2:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)
1. NÍTORÍ náà ìwọ ọmọ mi, jẹ́ alágbára nínú oore-ọ̀fẹ́ ti ń bẹ nínú Kírísítì Jésù.
2. Àwọn ohun ti ìwọ ti gbọ́ lọ́dọ̀ mi níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀, àwọn náà ni kí ìwọ fi lé àwọn olóòótọ́ ènìyàn lọ́wọ́, àwọn ti yóò lè máa kọ́ àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú.