2 Tímótíù 1:10-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. ṣùgbọ́n tí a fihàn níṣinṣinyìí nípa ìfarahàn Jésù Olùgbàlà wa, ẹni ti ó pa ikú run, tí ó sì mú ìyè àti àìkú wá sí ìmọ́lẹ̀ nípaṣẹ̀ ìyìnrere.

11. Fún ti ìyìnrere tí a yàn mi ṣe oníwàásù àti Àpósítélì àti olùkọ́.

12. Nítorí ìdí èyí ní èmi ṣe ń jìyà wọ̀nyí pẹ̀lú. Ṣùgbọ́n ojú kò tì mí: nítorí èmi mọ ẹni tí èmi gbàgbọ́, ó sì dá mi lójú pé, òun lè pa ohun ti mo fi lé e lọ́wọ́ mọ́ títí di ọjọ́ náà.

13. Ohun tí ó gbọ́ láti ọ̀dọ̀ mi, pa a mọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ rere nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ Kírísítì Jésù.

2 Tímótíù 1