2 Tẹsalóníkà 3:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Bẹ́ẹ̀ ni àwa kò sì jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, àwa ń ṣisẹ́ tọ̀sán-tòru kí a má baà di àjàgà sí ẹnikẹ́ni nínú yín lọ́rùn.

9. Àwa ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, kì í ṣe nítorí pé àwa kò ní ẹ̀tọ́ láti bèrè fún un, ṣùgbọ́n àwa ń fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ tí ẹ ó tẹ̀lé.

10. Nítorí nígbà tí àwà wà lọ́dọ̀ yín, a ṣe àwọn òfin wọ̀nyí fún-un yín pé, “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”

11. A gbọ́ pé àwọn kan wà láàrin yín tí wọn jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ ìmẹ́lẹ́. Wọ́n jẹ́ atọjúlé-kiri.

12. Ǹjẹ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwa ń pàṣẹ́ fún, tí a sì ń rọ̀ nínú Jésù Kírísítì Olúwa pé kí wọn ó máa ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ.

2 Tẹsalóníkà 3