2 Tẹsalóníkà 1:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó yẹ kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo nítorí yín, ará, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, nítorí pé ìgbàgbọ́ yín ń dàgbà gidigidi, àti ìfẹ́ olúkúlùkù yín gbogbo sí ara yín ń di púpọ̀.

4. Nítorí náà, àwa tìkara wa ń fi yín ṣògo nínú gbogbo inúnibíni àti wàhálà yín tí ẹ̀yin náà ń fi ara dà nínú gbogbo ìjọ.

5. Àwọn nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé òdodo ni ìdájọ́ Ọlọ́run àti pé ní torí èyí ni a ó kà yín yẹ fún ìjọba Ọlọ́run, nítorí èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú ṣe ń jìyà.

6. Olódodo ni Ọlọ́run: Òun yóò pọ́n àwọn tí ń pọ́n yín lójú, lójú,

7. Òun yóò sì fi ìtura fún ẹ̀yin tí a ti pọ́n lójú àti fún àwa náà pẹ̀lú. Èyí yóò sì se nígbà ìfarahàn Jésù Olúwa láti ọ̀run wá fún wá nínú ọwọ́ iná pẹ̀lú àwọn ańgẹ́lì alágbára.

2 Tẹsalóníkà 1