4. Ọba sì wí fún un pé, “Níbo ni ó gbé wà?”Síbà sì wí fún ọba pé, “Wò ó, òun wà ní ilé Mákírì, ọmọ Ámíélì, ní Lódébárì.”
5. Dáfídì ọba sì ránṣẹ́, ó sì mú un láti ilé Mákírì ọmọ Ámíélì láti Lódébárì wá.
6. Méfibóṣétì ọmọ Jónátaanì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù sì tọ Dáfídì wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì bú ọlá fún un.Dáfídì sì wí pé, “Méfibóṣétì!”Òun sì dáhún wí pé, “Wò ó, ìránṣẹ́ rẹ!”
7. Dáfídì sì wí fún un pé, “Má ṣe bẹ̀rù: nítorí pé nítòótọ́ èmi ó ṣe oore fún ọ nítorí Jónátanì baba rẹ, èmi ó sì tún fi gbogbo ilé Ṣọ́ọ̀lù baba rẹ fún ọ: ìwọ ó sì máa bá mi jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ mi.”