11. Ṣíbà sì wí fún ọba pé, “Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí Olúwa mi ọba ti pa láṣẹ fún ìránṣẹ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ náà ni ìránṣẹ́ rẹ ó ṣe.” Ọba sì wí pé, “Ní ti Méfibóṣétì, yóò máa jẹun ní ibi oúnjẹ mi, Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọba.”
12. Méfibóṣétì sì ní ọmọ kékeré kan, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Míkà. Gbogbo àwọn tí ń gbé ní ilé Síbà ni ó sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún Méfibóṣétì.
13. Méfibóṣétì sì ń gbé ní Jérúsálẹ́mù: òun a sì máa jẹun nígbà gbogbo ní ibi oúnjẹ́ ọba; òun sì yarọ ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ méjèèjì.