2 Sámúẹ́lì 6:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Bẹ́ẹ̀ ni Dáfídì àti gbogbo ilé Ísírẹ́lì sì gbé àpótí-ẹ̀rí Olúwa gòkè wá, pẹ̀lú ìhó ayọ̀, àti pẹ̀lú ìró ìpè.

16. Bí àpótí-ẹ̀rí Olúwa sì ti wọ ìlú Dáfídì wá; Mikali ọmọbìnrin Ṣọ́ọ̀lù sì wo láti ojú fèrèsé, ó sì rí Dáfídì ọba ń fò sòkè ó sì ń jó níwájú Olúwa; òun sì kẹ́gàn rẹ̀ ní ọkàn rẹ̀.

17. Wọ́n sì mú àpótí-ẹ̀rí Olúwa náà wá, wọ́n sì gbé e kalẹ̀ sípò rẹ̀ láàrin àgọ́ náà tí Dáfídì pa fún un: Dáfídì sì rubọ́ sísun àti ẹbọ ìrẹ́pọ̀ níwájú Olúwa.

2 Sámúẹ́lì 6