17. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Fílístínì gbọ́ pé, wọ́n ti fi Dáfídì jọba lórí Ísírẹ́lì, gbogbo àwọn Fílístínì sì gòkè wá láti wá Dáfídì; Dáfídì sì gbọ́, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìlú olódì.
18. Àwọn Fílístínì sì wá, wọ́n sì tẹ ara wọn ní àfonífojì Réfáímù.
19. Dáfídì sì béèrè lọ́dọ̀ Olúwa pé, “Kí èmi ó gòkè tọ àwọn Fílístínì bí? Ìwọ ó fi wọ́n lé mi lọ́wọ́ bí?” Olúwa sì wí fún Dáfídì pé, “Gòkè lọ, nítorí pé dájúdájú èmi ó fi àwọn Fílístínì lé ọ lọ́wọ́.”
20. Dáfídì sì dé Baal-Perasímù, Dáfídì sì pa wọ́n níbẹ̀, ó sì wí pé, “Olúwa ti ya lu àwọn ọta mi níwájú mi, gẹ́gẹ́ bí omi ti ń ya.” Nítorí náà ni òun ṣe pe orúkọ ibẹ̀ náà ni Baal-Perasímù.
21. Wọ́n sì fi òrìṣà wọn sílẹ̀ níbẹ̀, Dáfídì àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ sì kó wọn.