5. Àwọn ọmọ Rímímónì, ará Béérótì, Rákábù àti Báánà sì lọ wọ́n sì wá sí ilé Iṣíbóṣétì ní ọsán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́ kan-rí.
6. Sì wò ó, bí Olùsọ́ ẹnú ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárin ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú àlìkámà; (wọ́n sì gún un lábẹ́ inú: Rékábù àti Báánà arákùnrin rẹ̀ sì sá lọ).
7. Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sá lọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.
8. Wọ́n sì gbé orí Íṣíbóṣétì tọ Dáfídì wá ní Hébírónì, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Íṣíbóṣétì ọmọ Ṣọ́ọ̀lù ọ̀ta rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kíri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba Olúwa mi lónìí lára Ṣọ́ọ̀lù àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”
9. Dáfídì sì dá Rákábù àti Báánà arakùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rímímónì ará Béérótì lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú.