2 Sámúẹ́lì 3:29-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

29. Jẹ́ kí ó wà ní orí Jóabù, àti ní orí gbogbo ìdílé baba rẹ̀; kí a má sì fẹ́ ẹni ó tí ní àrùn ìṣun, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí ẹni tí ń tẹ ọ̀pá, tàbí ẹni tí a ó fi ìdà pa, tàbí ẹni tí ó ṣe aláìní oúnjẹ kù ní ilé Jóábù.”

30. (Jóábù àti Ábíṣáì arákùnrin rẹ̀ sì pa Ábínérì, nítorí pé òun ti pa Áṣáhélì arákùnrin wọn ní Gíbíónì ní ogun.)

31. Dáfídì sì wí fún Jóábù àti fún gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Ẹ fa aṣọ yín ya, kí ẹ̀yin sì mú aṣọ-ọ̀fọ̀, kí ẹ̀yín sì sunkún níwájú Ábínérì.” Dáfídì ọba tìkararẹ̀ sì tẹ̀lẹ́ pósí rẹ̀.

2 Sámúẹ́lì 3