1. Ogun náà sì pẹ́ títí láàrin ìdílé Ṣọ́ọ̀lù àti ìdílé Dáfídì: agbára Dáfídì sì ń pọ̀ si i, ṣùgbọ́n ìdílé Ṣọ́ọ̀lù ń rẹ̀yìn si i.
2. Dáfídì sì bí ọmọkùnrin ní Hébírónì: Ámónì ni àkọ́bí rẹ̀ tí Áhínóámù ará Jésírẹ́lì bí fún un.
3. Èkéjì rẹ̀ sì ni Kíléábù, tí Ábígáílì àya Nábálì ará Kárímẹ́lì;bí fún un ẹ̀kẹta sì ni Ábúsálómù ọmọ tí Máákà ọmọbìnrin Tálímáì ọba Gésúrì bí fún un.