44. “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí.
45. Àwọn àlejò wá láti tẹríba fún mi;bí wọ́n bá ti gbúròó mi, wọn á sì gbọ́ tèmi.
46. Àyà yóò pá àwọn àlejò,wọn ó sì fi ìbẹ̀rù sá kúrò níbi kọ́lọ́fín wọn.
47. “Olúwa ń bẹ́; olùbùkún sì ni àpáta mi!Gbígbéga sì ni Ọlọ́run àpáta ìgbàlà mi.
48. Ọlọ́run ni ẹni tí ń gbẹ̀san mi,àti ẹni tí ń rẹ àwọn ènìyàn sílẹ̀ lábẹ́ mi.
49. Àti ẹni tí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta mi.Ìwọ sì gbé mi sókè ju àwọn tí ó dìde sí mi lọ;ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ àwọn ọkùnrin oníwà ipá.