2 Sámúẹ́lì 22:41-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Ìwọ sì mú àwọn ọ̀ta mi pẹ̀yìndà fún mi,èmi ó sì pa àwọn tí ó kórira mi run.

42. Wọ́n wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti gbà wọ́n;wọ́n wo Olúwa, ṣùgbọ́n kò dá àwọn lóhùn.

43. Nígbà náà ni èmi sì gún wọn wẹ́wẹ́ bí erùpẹ̀ ilẹ̀,èmi sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ ìta, èmi sì tẹ́ wọn gbọrọ.

44. “Ìwọ sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ ìjà àwọn ènìyàn mi,ìwọ pá mí mọ́ ki èmi lè ṣe olórí àwọn àjèjì orílẹ̀-èdè.Àwọn ènìyàn tí èmi kòì tí mọ̀ yóò máa sìn mí.

2 Sámúẹ́lì 22