2 Sámúẹ́lì 22:34-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín;ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi.

35. Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;tóbẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.

36. Ìwọ sì ti fún mi ní àsàìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.

37. Ìwọ sì fi àyè ńlá sí abẹ́ ìṣísẹ̀ mi;tóbẹ́ẹ̀ tí ẹsẹ̀ mi kò fi yọ̀.

38. “Èmi ti lépa àwọn ọ̀tá mi, èmi sì ti run wọ́n,èmi kò pẹ̀yìndà títí èmi fi run wọ́n.

2 Sámúẹ́lì 22