2 Sámúẹ́lì 22:31-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. “Ọlọ́run yìí, pípé ni ọ̀nà rẹ̀;ọ̀rọ̀ Olúwa ni a ti dán wò.Òun sì niaṣà fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé e.

32. Nítorí ta ni Ọlọ́run, bí kò ṣe Olúwa?Ta ni àpáta, bí kò ṣe Ọlọ́run wa.

33. Ọlọ́run alágbára ni ó fún mi ní agbára,ó sì sọ ọ̀nà mi di títọ́.

34. Ó ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹṣẹ̀ àgbọ̀nrín;ó sì mú mi dúró ní ibi gígá mi.

35. Ó kọ́ ọwọ́ mi ní ogun jíjà;tóbẹ́ẹ̀ tí apá mi fa ọrun idẹ.

36. Ìwọ sì ti fún mi ní àsàìgbàlà rẹ̀, ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ sì ti sọ mí di ńlá.

2 Sámúẹ́lì 22