2 Sámúẹ́lì 22:24-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Èmi sì wà nínú ìwà-títọ́ sí í,èmi sì pa ara mi mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi.

25. Olúwa sì san fún mi gẹ́gẹ́ bí òdodo mi,gẹ́gẹ́ bí ìwà-mímọ́ mi níwájú rẹ̀.

26. “Fún aláàánú ni ìwọ ó fi ara rẹ̀ hàn ni aláàánú,àti fún ẹni-ìdúró-ṣinṣin ní òdodo ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní ìdúró-ṣinṣin ní òdodo.

27. Fún onínú-funfun ni ìwọ fi ara rẹ hàn ní funfun;àti fún ẹni-wíwọ́ ni ìwọ ó fi ara rẹ hàn ní wíwọ́.

28. Àwọn ènìyàn tí ó wà nínú ìyà ni ìwọ ó sì gbàlà;ṣùgbọ́n ojú rẹ wà lára àwọn agbéraga, láti rẹ̀ wọ́n sílẹ̀.

2 Sámúẹ́lì 22