2 Sámúẹ́lì 20:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ọba sì wí fún Ámásà pé, “Pè àwọn ọkùnrin Júdà fún mi níwọn ijọ́ mẹ́ta òní, kí ìwọ náà kí o sì wà níhìnyìí.”

5. Ámásà sì lọ láti pe àwọn ọkùnrin Júdà; ṣùgbọ́n ó sì dúró pẹ́ ju àkókò tí a fi fún un.

6. Dáfídì sì wí fún Ábíṣáì pé, “Nísinsinyìí Ṣébè ọmọ Bíkírì yóò ṣe wá ní ibi ju ti Ábúsálómù lọ; ìwọ mú àwọn ìránṣẹ́ olúwa rẹ, kí o sì lépa rẹ̀, kí ó má baà rí ìlú olódì wọ̀, kí ó sì bọ́ lọ́wọ́ wa.”

2 Sámúẹ́lì 20