11. Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin tí ó wà lọ́dọ̀ Jóábù sì dúró tì í, ó sì wí pé, “Ta ni ẹni tí ó fẹ́ràn Jóábù? Ta ni ó sì ń ṣe ti Dáfídì, kí ó máa tọ Jóábù lẹ́yìn.”
12. Ámásà sì ń yíràá nínú ẹ̀jẹ̀ láàrin ọ̀nà. Ọkùnrin náà sì ríi pé gbogbo ènìyàn sì dúró tì í, ó sì gbé Ámásà kúrò lójú ọ̀nà lọ sínú ìgbẹ́, ó sì fi aṣọ bò ó, nígbà tí ó rí i pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, á dúró.
13. Nígbà tí ó sì gbé e kúrò lójú ọ̀nà gbogbo ènìyàn sì tọ Jóábù lẹ́yìn láti lépa Ṣébà ọmọ Bíkírì.
14. Ó kọjá nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì sí Ábélì ti Bẹti Máákà, àti gbogbo àwọn ará Bérítì; wọ́n sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pẹ̀lú.
15. Wọ́n wá, wọ́n sì dó tì í ní Ábélì tí Bẹti Máákà, wọ́n sì mọ odí ti ìlú náà, odi náà sì dúró ti odi ìlú náà, gbogbo ènìyàn tí ń bẹ lọ́dọ̀ Jóábù sì ń gbìyànjú láti wó ògiri náà lulẹ̀.
16. Obìnrin ọlọ́gbọ́n kan sì kígbe sókè láti ìlú náà wá pé, “Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀! Èmi bẹ̀ yín, ẹsọ fún Jóábù pé: Súnmọ́ ìhìnyìí èmi ó sì bá a sọ̀rọ̀.”
17. Nígbà tí òun sì súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, obìnrin náà sì wí pé, “Ìwọ ni Jóábù bí?”Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi náà ni.”Obìnrin náà sì wí fún un pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́-bìnrin rẹ.”Òun sì dáhùn wí pé, “Èmi ń gbọ́.”