7. Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ: nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí: èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsinyìí.”
8. Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó lẹ́nu ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú Ọba: nítorí pé, Ísírẹ́lì ti sá, olúkúlukú sí àgọ́ rẹ̀.
9. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Ábúsálómù.
10. Ábúsálómù, tí àwa fi jọba lórí wa sì kú ní ogun: ǹjẹ́ èéṣe tí ẹ̀yín fi dákẹ́ tí ẹ̀yin kò sì sọ̀rọ̀ kan láti mú ọba padà wá?”
11. Dáfídì ọba sì ránṣẹ́ sí Sádókù, àti sí Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbà Júdà, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀.