6. Nítorí pé ìwọ fẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ, ìwọ sì kóríra àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Nítorí tí ìwọ wí lónìí pé, Ìwọ kò náání àwọn ọmọ ọba tàbí àwọn ìránṣẹ́; èmi sì rí lónìí pé, ìbáṣe pé Ábúsálómù wà láàyè, kí gbogbo wa sì kú lónìí, ǹjẹ́ ìbá dùn mọ́ ọ gidigidi.
7. Sì dìde nísinsin yìí, lọ, kí o sì sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ: nítorí pé èmi fi Olúwa búra, bí ìwọ kò bá lọ, ẹnìkan kì yóò bá ọ dúró ni alẹ́ yìí: èyí ni yóò sì burú fún ọ ju gbogbo ibi tí ojú rẹ ti ń rí láti ìgbà èwe rẹ wá títí ó fi di ìsinsinyìí.”
8. Ọba sì dìde, ó sì jókòó ní ẹnu ọ̀nà, Wọ́n sì wí fún gbogbo àwọn ènìyàn náà pé, “Wò ó, ọba jókòó lẹ́nu ọ̀nà.” Gbogbo ènìyàn sì wá sí iwájú Ọba: nítorí pé, Ísírẹ́lì ti sá, olúkúlukú sí àgọ́ rẹ̀.
9. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì ń bà ara wọn jà nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì, pé, “Ọba ti gbà wá là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, ó sì ti gbà wá kúrò lọ́wọ́ àwọn Fílístínì; òun sì wá sá kúrò ní ìlú nítorí Ábúsálómù.