2 Sámúẹ́lì 19:34-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Básíláì sì wí fún ọba pé, “Ọjọ́ mélòó ni ọdún ẹ̀mí mi kù, tí èmi ó fi bá ọba gòkè lọ sí Jérúsálẹ́mù

35. Ẹni ogbó ọgọ́rin ọdún sáà ni èmi lónìí: ǹjẹ́ èmi mọ ìyàtọ̀ nínú rere àti búburú? Ǹjẹ́ ìránṣẹ́ rẹ ló mọ adùn ohun tí òun ń jẹ tàbí ohun ti òun ń mu bí? Èmi tún lè mọ adùn ohùn àwọn ọkùnrin tí ń kọrin àti àwọn obìnrin tí ń kọ́rin bí, ǹjẹ́ nítorí kínni ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe jẹ́ ìyọnu síbẹ̀ fún Olúwa mi ọba.

36. Ìránṣẹ́ rẹ yóò sì sin ọba lọ díẹ̀ gòkè odò Jódánì; èésì ṣe tí ọba yóò fi san ẹ̀san yìí fún mi.

37. Èmi bẹ̀ ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ padà, èmi ó sì kú ní ìlú mi, a ó sì sin mí ní ibojì baba àti ìyá mi. Sì wo Kimhámù ìránṣẹ́ rẹ, yóò bá Olúwa mi ọba gòkè; ìwọ ó sì ṣe ohun tí ó bá tọ́ lójú rẹ fún un.”

38. Ọba sì dáhùn wí pé, “Kímhámù yóò bá mi gòkè, èmi ó sì ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀ fún un; ohunkóhun tí ìwọ bá sì béèrè lọ́wọ́ mi, èmi ó ṣeé fún ọ.”

39. Gbogbo àwọn ènìyàn sì gòkè odò Jódánì ọba sì gòkè; ọba sì fi ẹnu ko Básíláì lẹ́nu, ó sì súre fún un; òun sì padà sí ilé rẹ̀.

40. Ọba sì ń lọ́ sí Gílígálì, Kímhámù sì ń bà a lọ, gbogbo àwọn ènìyàn Júdà sì ń ṣe ìkẹ́ ọba, àti ààbò àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì.

2 Sámúẹ́lì 19