14. Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.”
15. Ọba sì padà, o sì wá sí odò Jódánì, Júdà sì wá sí Gílígálì láti lọ pàdé ọba, àti láti mú ọba kọjá odò Jódánì.
16. Ṣíméhì ọmọ Gérà, ará Bẹ́ńjámínì ti Báhúrímù, ó yára ó sì bá àwọn ọkùnrin Júdà sọ̀kalẹ̀ láti pàdé Dáfídì ọba.
17. Ẹgbẹ̀rún ọmọkùnrin sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nínú àwọn ọmọkùnrin Bẹ́ńjámínì, Ṣíbà ìránṣẹ́ ilé Ṣọ́ọ̀lù, àti àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún àti ogún ìránṣẹ́ sì pẹ̀lú rẹ̀; wọ́n sì gòkè odò Jódánì ṣáájú ọba.
18. Ọkọ̀ èrò kan ti rékọjá láti kó àwọn ènìyàn ilé ọba sí òkè, àti láti ṣe èyí tí ó tọ́ lójú rẹ̀.Ṣíméhì ọmọ Gérà wólẹ̀. Ó sì dojúbolẹ̀ níwájú ọba, bí ó tí gòkè odò Jódánì.
19. Ó sì wí fún ọba pé, “Kí Olúwa mi ó má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ sí mi lọ́rùn, má sì ṣe rántí àfojúdi tí ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣe ni ọjọ́ tí Olúwa mi ọba jáde ní Jérúsálẹ́mù, kí ọba má sì fi sí inú.
20. Nítorí pé ìránṣẹ́ rẹ mọ̀ pé èmi ti ṣẹ̀; sì wòó, mo wá lónìí yìí, ẹni àkọ́kọ́ ní gbogbo ìdílé Jósẹ́fù tí yóò sọ̀kalẹ̀ wá pàdé Olúwa mi ọba.”
21. Ṣùgbọ́n Ábíṣáì ọmọ Serúíà dáhùn ó sì wí pé, “Kò há tọ́ kí a pa Síméì nítorí èyí? Nítorí pé òun ti bú ẹni àmì òróró Olúwa.”
22. Dáfídì sì wí pé, “Kí ni èmi ní ṣe pẹ̀lú yín, ẹ̀yin ọmọ Serúíà tí ẹ dàbí ọ̀ta fún mi lónìí? A há lè pa ènìyàn kan lónìí ní Ísírẹ́lì? Tàbí èmi kò ha mọ̀ pé lónìí èmi ni ọba Ísírẹ́lì.”