2 Sámúẹ́lì 19:11-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Dáfídì ọba sì ránṣẹ́ sí Sádókù, àti sí Ábíátarì àwọn àlùfáà pé, “Sọ fún àwọn àgbà Júdà, pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá sí ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ gbogbo Ísírẹ́lì sì ti dé ọ̀dọ̀ ọba àní ní ilé rẹ̀.

12. Ẹ̀yin ni ara mi, ẹ̀yin ni egungun mi, àti ẹran ara mi: èésì ti ṣe tí ẹ̀yin fi kẹ́yìn láti mú ọba padà wá.’

13. Kí ẹ̀yin sì wí fún Ámásà pé, ‘Egungun àti ẹran ara mi kọ́ ni ìwọ jẹ́ bí? Kí Ọlọ́run ó ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí ìwọ kò ba ṣe olórí ogun níwájú mi títí, ní ipò Jóábù.’ ”

14. Òun sì yí gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà lọ́kàn padà àní bí ọkàn ènìyàn kan; wọ́n sì ránṣẹ́ sí ọba, pé, “Ìwọ padà àti gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ.”

2 Sámúẹ́lì 19