12. Ọkùnrin náà sì wí fún Jóábù pé, “Bí èmi tilẹ̀ gba ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà sí ọwọ́ mí, èmi kì yóò fi ọwọ́ mi kan ọmọ ọba: nítorí pé àwa gbọ́ nígbà tí ọba kìlọ̀ fún ìwọ àti Ábíṣáì, àti Ítaì, pé, ‘Ẹ kíyèsí i, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọwọ́ kan ọ̀dọ́mọkùnrin náà Ábúsálómù.’
13. Bí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀ èmi ìbá ṣe sí ara mi: nítorí pé kò sí ọ̀ràn kan tí ó pamọ́ fún ọba, ìwọ tìkárarẹ̀ ìbá sì kọjú ìjà sí mi pẹ̀lú.”
14. Jóábù sì wí pé, “Èmi kì yóò dúró bẹ́ẹ̀ níwájú rẹ.” Ó sì mú ọ̀kọ̀ mẹ́ta lọ́wọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ́n gún Ábúsálómù ní ọkàn, nígbà tí ó sì wà láàyè ní agbede-méjì igi óákù náà.
15. Àwọn ọ̀dọ́mọdékùnrin mẹ́wàá tí ó máa ń ru ìhámọ́ra Jóábù sì yí Ábúsálómù ká, wọ́n sì kọlù ú, wọ́n sì pa á,
16. Jóábù sì fun ìpè, àwọn ènìyàn náà sì yípadà láti máa lépa Ísírẹ́lì: nítorí Jóábù ti pe àwọn ènìyàn náà padà.
17. Wọ́n sì gbé Ábúsálómù, wọ́n sì sọ ọ́ sínú ihò ńlá kan ní igbó náà, wọ́n sì kó òkúta púpọ̀ jọ sí i lórí, gbogbo Ísírẹ́lì sì sá, olúkúlùkù sí inú àgọ́ rẹ̀.
18. Ábúsálómù ní ìgbà ayé rẹ̀, sì mọ ọ̀wọ̀n kan fún ara rẹ̀, tí ń bẹ ní àfonífojì ọba: nítorí tí ó wí pé, Èmi kò ní ọmọkùnrin tí yóò pa orúkọ mi mọ́ ní ìrántí: òun sì pe ọ̀wọ̀n náà nípa orúkọ rẹ̀: a sì ń pè é títí di òní, ní ọ̀wọ́n Ábúsálómù.
19. Áhímásì ọmọ Sádókù sì wí pé, “Jẹ́ kí èmi ó súré nísinsin yìí, kí èmi sì mú ìhìn tọ ọba lọ, bí Olúwa ti gbẹ̀san rẹ̀ lára àwọn ọ̀ta rẹ̀.”
20. Jóábù sì wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò mù ìhìn lọ lónìí, ṣùgbọ́n ìwọ ó mú lọ ní ijọ́ mìíràn: ṣùgbọ́n lónìí yìí ìwọ kì yóò mú ìhìn kan lọ, nítorí tí ọmọ Ọba ṣe aláìsí.”