22. Wọ́n sì tẹ́ àgọ́ kan fún Ábúsálómù ní òrùlé; Ábúsálómù sì wọlé tọ àwọn obìnrin baba rẹ̀ lójú gbogbo Ísírẹ́lì.
23. Ìmọ̀ Áhítófélì tí ó máa ń gbà ni ìgbà náà, ó dàbí ẹni pé ènìyàn béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run: bẹ́ẹ̀ ni gbogbo ìmọ̀ Áhítófélì fún Dáfídì àti fún Ábúsálómù sì rí.