2 Sámúẹ́lì 14:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ọba sì bi í léèrè pé, “Kin ni o ṣe ọ́?”Òun sì dáhùn wí pé, “Nítòótọ́ opó ni èmi ń ṣe, ọkọ mi sì kú.

6. Ìránṣẹ́-bìnrin rẹ̀ sì ti ní ọmọkùnrin méjì, àwọn méjèèjì sì jọ jà lóko, kò sì si ẹni tí yóò là wọ́n, èkínní sì lu èkejì, ó sì pa á.

7. Sì wò ó, gbogbo ìdílé dìde sí ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀, wọ́n sì wí pé, Fi ẹni tí ó pa arákùnrin rẹ fún wa, àwa ó sì pa á ní ipò ẹ̀mi arákùnrin rẹ̀ tí ó pa, àwa ó sì pa àrólé náà run pẹ̀lú: wọn ó sì pa iná mi tí ó kù, wọn kì yóò sì fi orúkọ tàbí ẹni tí ó kú silẹ̀ fún ọkọ mi ní ayé.”

8. Ọba sì wí fún obìnrin náà pé, “Lọ sí ilé rẹ̀, èmi ó sì kìlọ̀ nítorí rẹ.”

9. Obìnrin ará Tékóà náà sì wí fún ọba pé, “Olúwa mi, ọba, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wà lórí mi, àti lorí idilé baba mí; kí ọba àti ìtẹ́ rẹ̀ ó jẹ́ aláìlẹ́bi.”

10. Ọba sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ sí ọ, mú Olúwa rẹ̀ tọ̀ mí wá, òun kì yóò sì tọ́ ọ mọ́.”

11. Ó sì wí pé, “Èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí ọba ó rántí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má ṣe ní ipá láti ṣe iparun, kí wọn o má bá a pa ọmọ mi!”Òun sì wí pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ láàyè ọ̀kan nínú irun orí ọmọ rẹ ki yóò bọ sílẹ̀.”

2 Sámúẹ́lì 14