2 Sámúẹ́lì 12:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sì bí léèrè pé, “Kí lèyí tí ìwọ ṣe yìí? Nítorí ọmọ náà nígbà tí ó ń bẹ láàyè ìwọ gbààwẹ̀, o sì sunkún; ṣùgbọ́n nígbà tí ọmọ náà kú, ó dìde ó sì jẹun.”

22. Ó sì wí pé, “Nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, èmi gbààwẹ̀, èmi sì sunkún: nítorí tí Èmi wí pé, ‘Ta ni ó mọ̀ bí Ọlọ́run ó ṣàánú mi, kí ọmọ náà le yè.’

23. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti kú, nítorí kín ni èmi ó ṣe máa gbààwẹ̀? Èmi ha tún lè mú-un padà bí? Èmi ni yóò tọ̀ ọ́ lọ, òun kì yóò sì tún tọ̀ mí wá.”

24. Dáfídì sì ṣìpẹ̀ fún Bátíṣébà aya rẹ̀, ó sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a dàpọ̀: òun sì bí ọmọkùnrin kan, Dáfídì sì sọ orúkọ rẹ̀ ní Sólómónì: Olúwa sì fẹ́ ẹ.

25. Ó sì rán Nátanì wòlíì, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jédídíáyà, nítorí Olúwa.

26. Jóábù sì bá Rábà ti àwọn ọmọ Ámónì jagun, ó sì gba ìlú ọba wọn.

27. Jóábù sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Dáfídì, ó sì wí pé, “Èmi ti bá Rábà jà, èmi sì ti gba àwọn ìlú olomi.

28. Ǹjẹ́ nítorí náà kó àwọn ènìyàn ìyókù jọ, kí o sì dó ti ìlú náà, kí o sì gbà á, kí èmi má báà gba ìlú náà kí a má baà pè é ní orúkọ mi.”

2 Sámúẹ́lì 12