2 Sámúẹ́lì 12:10-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ǹjẹ́ nítorí náà idà kì yóò kúró ní ilé rẹ títí láé; nítorí pé ìwọ gàn mí, ìwọ sì mú aya Úráyà ará Hítì láti ṣe aya rẹ.’

11. “Bàyìí ni Olúwa wí, Kíyèsí i, ‘Èmi ó jẹ́ kí ibi kí ó dìde sí ọ láti inú ilé rẹ wá, èmi ó sì gba àwọn obìnrin rẹ lójú rẹ, èmi ó sì fi wọ́n fún aládúgbò rẹ, òun ó sì bá àwọn obìnrin rẹ sùn níwájú òòrun yìí.

12. Àti pé ìwọ ṣe é ní ìkọ̀kọ̀: Ṣùgbọ́n èmi ó ṣe nǹkan yìí níwájú gbogbo Ísírẹ́lì, àti níwájú òòrun.’ ”

13. Dáfídì sì wí fún Nátanì pé, “Èmi ṣẹ̀ sí Olúwa!”Nátanì sì wí fún Dáfídì pé, “Olúwa pẹ̀lú sì ti mú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kúrò; ìwọ kì yóò kú.

14. Ṣùgbọ́n nítorí nípa ìwà yìí, ìwọ fi àyè sílẹ̀ fún àwọn ọ̀ta Olúwa láti sọ ọ̀rọ̀ òdì, ọmọ náà tí a ó bí fún ọ, kíkú ní yóò kú.”

15. Nátanì sì lọ sí ilé rẹ̀ Olúwa sì fi àrùn kọlu ọmọ náà tí obìnrin Úráyà bí fún Dáfídì, ó sì ṣe àìsàn púpọ̀.

16. Dáfídì sì bẹ Ọlọ́run nítorí ọmọ náà, Dáfídì sì gbààwẹ̀, ó sì wọ inú ilé lọ, ó sì dúbúlẹ̀ lorí ilé ni orú náà.

17. Àwọn àgbà ilé rẹ̀ sì dìde tọ̀ ọ́ lọ, láti gbé e dìde lórí ilé: ó sì kọ̀, kò sì bá wọn jẹun.

18. Ní ijọ́ keje, ọmọ náà sì kú. Àwọn ìránṣẹ́ Dáfídì sì bẹ̀rù láti wí fún un pé, ọmọ náà kú: nítorí tí wọ́n wí pé, “Kíyèsí i, nígbà tí ọmọ náà ń bẹ láàyè, àwa sọ̀rọ̀ fún un, òun kọ̀ si gbọ́ ohùn wa! Ǹjẹ́ yóò ti ṣe ara rẹ̀ ní ìṣẹ́ tó, bí àwa bá wí fún un pé, ọmọ náà kú.”

2 Sámúẹ́lì 12