2 Sámúẹ́lì 1:24-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. “Ẹ̀yin ọmọbìnrin Ísírẹ́lì,ẹ sunkún lórí Ṣọ́ọ̀lù,ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín,ẹni tí ó fí wúrà sí ara aṣọ yín.

25. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun!Jónátánì, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.

26. Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jónátanì arákùnrin mi;ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi.Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu,ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.

27. “Wò ó bí alágbára ti ṣubú!Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”

2 Sámúẹ́lì 1