2 Ọba 8:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nísin yìí, Èlíṣà wí fún obìnrin náà tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin jí pàdà sáyé pé, “jáde lọ pẹ̀lú ìdílé rẹ kí o sì lọ dúró fún ìgbà díẹ̀ ní ibíkíbi tí o bá le dúró sí, nítorí Olúwa ti pàṣẹ ìyàn ní ìlú tí yóò lò tó ọdún méje.”

2. Obìnrin náà tẹ̀ ṣíwájú gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ti sọ. Òun àti ìdílé rẹ̀ sá lọ, wọ́n sì dúró ní ilé àwọn ará Fílístínì fún ọdún méje.

2 Ọba 8