5. Ní àfẹ̀mójúmọ́ wọ́n dìde wọ́n sì lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà. Nígbà tí wọ́n dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó náà, kò sí ọkùnrin kan níbẹ̀,
6. Nítorí tí Olúwa jẹ́ kí àwọn ará Síríà gbọ́ ìró kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin àti ogun ńlá, wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wò ó, ọba Ísírẹ́lì ti bẹ ogun àwọn Hítì àti àwọn ọba Ígíbítì láti dojúkọ mú u wá!”
7. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì dìde wọ́n sì sálọ ní àfẹ̀mọ́júmọ́ wọ́n sì fi àgọ́ wọn sílẹ̀ àti ẹṣin wọn àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. Wọ́n sì fi ibùdó sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà, wọ́n sì sálọ fún ẹ̀mí wọn.
8. Nígbà tí àwọn ọkùnrin tí ó ní àrùn ẹ̀tẹ̀ dé ẹ̀gbẹ́ ibùdó wọ́n sì wọ inú ọ̀kan nínú àgọ́ náà. Wọ́n jẹ wọ́n sì mu, wọ́n sì kó fàdákà, wúrà àti ẹ̀wù, wọ́n sì lọ. Wọ́n sì wọ àgọ́ mìíràn lọ, wọ́n kó àwọn nǹkan láti ibẹ̀ wọ́n sì kó wọn pamọ́ pẹ̀lú.
9. Nígbà náà wọ́n wí fún ara wọn pé, “Àwa kò ṣe ohun rere. Oni yìí jẹ́ ọjọ́ ìròyìn rere àwa si paamọ́ ara wa. Tí àwa bá dúró títí di àfẹ̀mọ́júmọ́, ìjayà yóò jẹ́ ti wa. Ẹ jẹ́ kí a lọ ní ẹ̀ẹ̀kan kí a lọ ròyìn èyí fún àwọn ilé ọba.”
10. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì lọ wọ́n sì pe àwọn oníbodè wọ́n sì wí fún wọn pé, “Àwa lọ sí ibùdó àwọn ará Síríà kò sì sí ọkùnrin kankan níbẹ̀ tàbí ohùn ènìyàn kan àyàfi ẹṣin tí a so àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àwọn àgọ́ náà sì wà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà.”