2 Ọba 6:9-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ènìyàn Ọlọ́run rán iṣẹ́ sí ọba Ísírẹ́lì, “kíyèsí ara láti kọjá ní ibẹ̀ yẹn, nítorí pé ará Árámù wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ síbẹ̀.”

10. Bẹ́ẹ̀ ni ọba Ísírẹ́lì wo ibi tí ènìyàn Ọlọ́run náà fi hàn, ní ẹ̀ẹ̀kan sí i Èlíṣà kìlọ̀ fún ọba, bẹ́ẹ̀ ni ó wà lórí sísọ ní ibẹ̀.

11. Èyí mú ọba Árámù bínú. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ṣé ìwọ kò ní sọ fún un èwo nínú wa ni ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọba Ísírẹ́lì?”

2 Ọba 6