2 Ọba 6:12-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. “Kò sí ọ̀kan nínú wa, Olúwa ọba mi,” ọ̀kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ sì wí pé, “ṣùgbọ́n Èlíṣà, wòlíì tí ó wà ní Ísírẹ́lì, sọ fún ọba Ísírẹ́lì ọ̀rọ̀ gangan tí ó sọ nínú yàrá rẹ̀.

13. “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà,” ọba pa á láṣẹ, “Kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá. “Ó wà ní Dótanì.”

14. Nígbà náà ó rán àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ àti ogun ńlá tí ó le síbẹ̀. Wọ́n sì lọ ní alẹ́ wọ́n sì yí ìlú náà ká.

2 Ọba 6