2 Ọba 4:35-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Èlíṣà yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì sí ojú rẹ̀.

36. Èlíṣà sì pe Géhásì ó sì wí pé, “Pe ará Súnémù.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.”

37. Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ ṣíwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

2 Ọba 4