2 Ọba 4:30-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàyè, èmi kò níí fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e.

31. Géhásì sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn dídún. Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì padà lọ láti lọ bá Èlíṣà láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”

32. Nígbà tí Èlíṣà dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn.

33. Ó sì wọ ilé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

2 Ọba 4