2 Ọba 4:28-39 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. “Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, Olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pe kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?”

29. Èlíṣà wí fún Géhásì pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.”

30. Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láàyè, èmi kò níí fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e.

31. Géhásì sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn dídún. Bẹ́ẹ̀ ni Géhásì padà lọ láti lọ bá Èlíṣà láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”

32. Nígbà tí Èlíṣà dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn.

33. Ó sì wọ ilé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa.

34. Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná.

35. Èlíṣà yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì sí ojú rẹ̀.

36. Èlíṣà sì pe Géhásì ó sì wí pé, “Pe ará Súnémù.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.”

37. Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ ṣíwájú ẹṣẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ Orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

38. Èlíṣà padà sí Gílgálì ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì ṣe ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”

39. Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà ìgbẹ́. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ.

2 Ọba 4