7. Wọ́n sì pa ọmọ Ṣédékáyà níwájú rẹ̀, wọ́n sì yọ ojú rẹ̀ jáde, wọn dèé pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n idẹ wọ́n sì gbe é lọ sí Bábílónì.
8. Ní ọjọ́ kèje ní oṣù karùn ún, ní ọdún ìkọkàndínlógún ti Nebukadinésárì ọba Bábílónì, Nebukadinéṣárì olórí ẹ̀sọ́ ti ọba ìjòyè ọba Bábílónì wá sí Jérúsálẹ́mù
9. ó sì finá sí ilé Olúwa, ilé ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti gbogbo ilé pàtàkì, ó jó wọn níná.
10. Gbogbo àwọn ọmọ ogun Bábílónì, lábẹ́ olórí ti ìjọba ẹ̀sọ́, wó ògiri tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká lulẹ̀.