5. Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Júdà láti ṣun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Júdà àti àwọn tí ó yí Jérúsálẹ́mù ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Báálì, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.
6. Ó mú ère òrìṣà láti ilé Olúwa sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kídírónì ní ìta Jérúsálẹ́mù, ó sì ṣun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí atíkè ó sì fọ́n ekuru náà sórí iṣà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.
7. Ó sì wó ibùgbé àwọn tí ń ṣe panṣágà lọ́kùnrin o tí ojúbọ wọn lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún Áṣérà (òriṣà).
8. Jòṣíáyà kó gbogbo àwọn àlùfáà láti àwọn ìlú Júdà ó sì ba ibi mímọ́ wọ̀n-ọn-nì jẹ́ láti Gébà sí Béríṣébà, níbi tí àwọn àlùfáà ti ṣun tùràrí. Ó wó àwọn ojúbọ lulẹ̀ ní ẹnu ìlẹ̀kùn—ní ẹnu ọ̀nà à bá wọlé ti Jóṣúà, baálẹ̀ ìlú ńlá tí ó wà ní apá òsì ẹnu ìlẹ̀kùn ìlú ńlá.