2 Ọba 21:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó sì tún ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekíáyà tí ó parun kọ́. Ó sì tún gbé pẹpẹ dìde fún Báálì ó sì ṣe ère-òrìṣà, gẹ́gẹ́ bí Áhábù ọba Ísírẹ́lì ti ṣe. Ó sì tẹríba sí gbogbo ogun ọ̀run, ó sì ń sìn wọ́n.

4. Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jérúsálẹ́mù ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.”

5. Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú.

6. Ó fi ọmọ ara rẹ̀ rúbọ̀ nínú iná, a máa ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ àti àlùpàyídà, ó sì máa ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó hùwà búburú púpọ̀ ní ojú Olúwa láti mú un bínú.

2 Ọba 21