2 Ọba 21:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Olúwa sì wí nípasẹ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì pé:

11. “Mánásè ọba Júdà ti ṣe ẹ̀ṣẹ̀ ohun ìríra. Ó ti ṣe ohun búburú jùlọ ju àwọn ará Ámórì lọ ẹni tí ó ti wà ṣáájú rẹ̀ tí ó sì ti ṣáájú Júdà sínú ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀lú àwọn ère rẹ̀.

12. Nítorí náà èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Ísírẹ́lì, wí: Èmi le è lọ mú irú ibi báyìí wá sórí Jérúsálẹ́mù àti Júdà kí gbogbo etí olúkúlùkù tí ó gbọ́ nípa rẹ̀ le è hó.

13. Èmi yóò sì nà okùn ìwọ̀nkan tí a lò lórí Jérúsálẹ́mù àti lórí Ṣamáríà àti òjé ìdiwọ̀n ti a lòlò lórí ilé Áhábù. Èmi yóò sì nu Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọkàn tí ń nu àwokòtò nù ti o n nù un tí o sì ń dorí rẹ̀ kodò.

14. Èmi yóò sì kọ ìyókù àwọn ìní mi sílẹ̀ èmi yóò sì kó wọn lé àwọn ọ̀ta wọn lọ́wọ́. Wọn yóò sì di ìkógun àti ìjẹ fún gbogbo àwọn ọ̀ta wọn,

15. nítorí pé wọ́n ti ṣe búburú ní ojú mi, wọ́n sì ti mú mi bínú láti ọjọ́ tí babańlá wọn ti jáde wá láti Éjíbítì títí di òní yìí.”

2 Ọba 21