2 Ọba 21:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mánásè jẹ́ ẹni ọdún méjìlá nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ìjọba, ó sì jọba ní Jérúsálẹ́mù fún ọdún márùndínlọ́gọ́ta (55). Orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Héfisíbà.

2. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

2 Ọba 21