7. Nígbà náà ni Àìṣáyà wí pé, “Mú ọ̀pọ̀tọ́ tí a sù bí i gàrí.” Wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sì fi sí owo náà, ara rẹ̀ sì yá.
8. Heṣekáyà sì béèrè lọ́wọ́ Àìṣáyà pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmìn pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”
9. Àìṣáyà dáhùn pé, “Èyí ni àmìn tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”
10. “Ó jẹ́ ohun ìrọ̀rùn fún òjìji láti lọ ṣíwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá,” Heṣekáyà wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, jẹ́ kí ó lọ padà ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá.”
11. Nígbà náà wòlíì Àìṣáyà ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Áhásì.