17. Ọba Ásíríà rán alákòóṣo gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí ó pọ̀, láti Lákísì sí ọba Heṣekáyà ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n wá sí òkè Jérúsálẹ́mù wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá Alágbàfọ̀.
18. Wọ́n sì pe ọba; àti Eliákímù ọmọ Hílíkíyà ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọkùnrin Ásáfù tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn.
19. Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Heṣekáyà pé:“ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ: Lórí kí ni ìwọ ń dá ìgbóyà rẹ̀ yìí?
20. Ìwọ wí pé ìwọ ni ẹ̀tà àti ti ogun alágbára ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo nìkan, lórí ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi?
21. Wò ó Nísinsìn yìí ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Éjíbítì, ẹ̀rún igi pẹlẹbẹ ọ̀pá ìyè lórí ọ̀pá, èyí tí yóò wọ inú ọwọ́ ọkùnrin tí ó sì pa á lára tí ó bá fi ara tìí Irú rẹ̀ ni Fáráò ọba Éjíbítì fún gbogbo àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀ wọn lé e.
22. Tí ìwọ bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀ wa lé Olúwa Ọlọ́run.” Òun ha kọ́ ní ẹnìkan náà tí ibi gíga àti àwọn pẹpẹ tí Heṣekáyà mú kúrò, tí ó wí fún Júdà àti Jérúsálẹ́mù pé, “O gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí ní Jérúsálẹ́mù”?
23. “ ‘Wá Nísinsìn yìí, ṣe àdéhùn pẹ̀lú ọ̀gá mi, ọba Áṣíríà: Èmi yóò sì fún ọ ní ẹgbàá ẹṣin (2000) tí ìwọ bá lè kó àwọn tí yóò gùn ún sí orí rẹ!
24. Báwo ni ìwọ yóò ṣe le padà sẹ́yìn ọ̀kan lára àwọn oníṣẹ́, tí ó gbẹ̀yìn lára àwọn oníṣẹ́ ọ̀gá mi, tí ó bá tilẹ̀ jẹ́ pé; ẹ̀yin gbẹ́kẹ̀ yín lé Éjíbítì fún àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin?
25. Síwájú síi, èmi ti wá láti mú àti láti parun ibíyìí láìsí ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ sọ fún mi pé kí n yára láti yan lórí ìlú yìí, kí n sì paárun.’ ”
26. Nígbà náà Éláékímù ọmọ Hílíkíáyà, àti ṣébínà àti Jóà sọ fún olùdarí pápá pé, “Jọ̀wọ́ sọ̀rọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ ní èdè Ṣíríà, nítorí ti ó tí yé wa, má ṣe sọ̀rọ̀ fún wa pẹ̀lú èdè Hébérù ní etí ìgbọ́ àwọn ènìyàn tí ń bẹ lórí odi.”
27. Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀ga mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sìí ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odo-ta ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?”
28. Nígbà náà aláṣẹ dìdé ó sì pè jáde ní èdè Hébérù pé, “Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba Ásìría!