2 Ọba 18:16-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. Ní àkókò yìí Heṣekáyà ọba Júdà ké wúrà tí ó wà ní ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Olúwa, kúrò àti ti òpó tí Heṣekáyà ọba Júdà ti gbéró ó sì fi fún ọba Ásíríà.

17. Ọba Ásíríà rán alákòóṣo gíga jùlọ, ìjòyè pàtàkì àti àwọn adarí pápá pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun tí ó pọ̀, láti Lákísì sí ọba Heṣekáyà ní Jérúsálẹ́mù. Wọ́n wá sí òkè Jérúsálẹ́mù wọ́n sì dúró ní etí ìdarí omi àbàtà òkè, ní ojú ọ̀nà tó lọ sí òpópó pápá Alágbàfọ̀.

18. Wọ́n sì pe ọba; àti Eliákímù ọmọ Hílíkíyà ẹni tí í ṣe ilé olùtọ́jú, Ṣébínà akọ̀wé, àti Jóà ọmọkùnrin Ásáfù tí ó jẹ́ akọ̀wé ìrántí jáde pẹ̀lú wọn.

19. Olùdarí pápá wí fún wọn pé, “Sọ fún Heṣekáyà pé:“ ‘Èyí ni ohun tí ọba ńlá, ọba Ásíríà sọ: Lórí kí ni ìwọ ń dá ìgbóyà rẹ̀ yìí?

20. Ìwọ wí pé ìwọ ni ẹ̀tà àti ti ogun alágbára ṣùgbọ́n ìwọ sọ̀rọ̀ òfìfo nìkan, lórí ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀ rẹ lé tí ìwọ fi ń ṣe ọ̀tẹ̀ sí mi?

2 Ọba 18