2 Ọba 15:25-27 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ọ̀kan lára àwọn olórí ìjòyè rẹ̀ Pékà ọmọ Remalíà, dìtẹ̀ síi. Ó mú àádọ́ta àwọn ọkùnrin ti àwọn ará Gílíádì pẹ̀lú u rẹ̀. Ó pa Pékáhíà pẹ̀lú Árígóbù àti Áríè ní Kítadélì ti ààfin ọba ní Ṣamáríà. Bẹ́ẹ̀ ni Pékà pa Pékáhíà, ó sì rọ́pò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba.

26. Fún ti ìyókù iṣẹ́ ìjọba Pékáhíà, gbogbo ohun tí ó ṣe, ni a kọ sínú ìwé ìtàn ayé àwọn ọba Ísírẹ́lì

27. Ní ọdún kejìléláàdọ́ta Ásáríyà ọba Júdà, Pékà ọmọ Rèmálíà di ọba Ísírẹ́lì ní Ṣamáríà. Ó sì jọba fún ogún ọdún.

2 Ọba 15